Awọn itan Bibeli ti inu iwe yi yio jẹ iranwọ fun awọn ọmọde lati ranti pe ohunkohun yo wu ti ńsẹlẹ ninu aiye wọn tabi ni ayika wọn, Ọlọrun ntọju, bẹni O si ńsọ wọn lọsan ati loru. Ko dabi awọn obi wa, Ọlọrun ki i sun tabi ko sarẹ. Ọlọrun si mọ ọjọ waju. O jẹ olododo ati Ẹniti ńpa adehun Rẹ mọ.
Ninu iwe yi, Philip O. Akinyẹmi fihan bi Ọlọrun ti dabo bo awọn ọpọlọpọ enia ninu Bibeli bẹni O si ńse titi di oni.
• Josẹfu ninu Ihò.
• Mose li ẹba odò.
• Samuẹli ni kekere kuro lọdọ awon obi rẹ.
• Dafidi ba akikanju Goliati ja o si bori.
• Ọlọrun dabo bo ọmọ-ọwọ Joaṣi nigbati a pa gbogbo iru-ọmọ ọba run.
• Awọn ọdọmọkunrin Heberu mẹta ninu adágún iná.
• Danìẹli ninu ihò kiniun.
• Jona ninu ẹja.
• Peteru ninu tubu.
• Angẹli awọn ọmọde ńsọ wọn.